Yoruba poetry in praise of Olodumare

The remarkable Mayowa Adeyemo performs a powerful poem in praise of Olodumare, the Supreme Deity.

 

Original:

Odíderé ayékòótá máa wolè máràba
Odéderé ayébòútó máa wolè máràba
oò ri’ báyé nwá doríto dò tó dobúépo
ọmọ ò gbọ́ tí baba mo, baba ò gbó dimọ má, aya ò gbọ́ lọkọ mo
gbogbo rè wá polúkúrámusu nílé ayé o
Elédùmarè e, Olódù só màre
Òbá wá bá wa túnlé ayé se
Káyé ó máse dàrú má
Káyé ó rójú, káyé ó ráàyè
Kóòdè ó gba gbogbo wa nílé ayé
Torílé ayé yìí kansoso la wá
Àjò sì nilé ayé
Gbogbo wa la ó padà relí bóbá dọjọ́ kaa
Elédùmarè o o o
Ìwọ mà lọ̀mọ̀ràn tí moyún ìgbín nínú ìkọrọhua
Ìwọ mà leni tó tọgbọ́n mọgbá orí
Ìwọ mà leni tó dá gbogbo wa rílé ayé
Tí wọ́n ti ń pelé ayé nílé dúníyàn o
Elédùmarè ọba toto bọ bí orí
Bíyá tín bì ó díè kórí ire ó lè wá
Bo lè dámí l’óhùn gbogbo ohun tí mo bá
bèrè lọ́wọ́ ò ré lújúọ tòní o
Oba atérere káré ayé, Ọba kòṣeuntì
Òbàmùbárá matéré bamba
Elédùmarè
Ènìyàn wèròwèsò tí ò sée lowó wàdùwàdù mú
Enítóbá tasè àgèsè pérén
Kódà á sanwó láyé, á wá lo rèé sekà lórun ni
Elédùmarè o o o
Ọba ńlá, tí ò seé gbíjá, ọba tí ò seé gbìjà
Torí mọ súmóba níwọ̀n egbèje
Mo jìnnà sóba níwọ̀n egbejà
mi ò mà róba fín torá róba fiń loba ń pa
Ọba tótó bí aró, ọba rèrè bí osùn
Eléní àtèká gbogbo mekùn oòyè
Òpó àndù oyè
Ọba tí wọ́n kìí bá du oyè láíláí
L’elédùmarè ọba tèmi
Ọ̀bá dákun o gbébè mi
Ọ̀bá dákun o gbébè mi
Káyé ó ńjú fún wa
Káyé ó ńjú fún wa
Kílè yí ó sàn wá
Kílè yíí ó san wá
Kámáse rógun àdáyà
Kámáse rógun àgbédá
Kámáse rógun àkóbá
Lólá Elédùmarè jóo bá jé gbó àdúrà wa
Mose tótó, mo se sákì olú
Gbogbo èyí náà, ko ba lè gbóhùn èbè mi ni
Ọ̀bá dákun wá gbọ́ o o o

enso-799284-1280x768